Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
18 verses
1NITORI nkan yi ni mo rò li aiya mi, ani lati wadi gbogbo eyi pe, olododo, ati ọlọgbọ́n, ati iṣẹ wọn, lọwọ Ọlọrun li o wà: ifẹni ati irira, kò si ẹniti o mọ̀, gbogbo eyi wà niwaju wọn.
2Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn: ohun kanna li o nṣe si olododo, ati si ẹni buburu; si enia rere, ati si mimọ́ ati si alaimọ́; si ẹniti nrubọ, ati si ẹniti kò rubọ: bi enia rere ti ri, bẹ̃ li ẹ̀lẹṣẹ; ati ẹniti mbura bi ẹniti o bẹ̀ru ibura.
3Eyi ni ibi ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn, pe iṣẹ kanna ni si gbogbo wọn: ati pẹlu, aiya awọn ọmọ enia kún fun ibi, isinwin mbẹ ninu wọn nigbati wọn wà lãye, ati lẹhin eyini; nwọn a lọ sọdọ awọn okú.
4Nitoripe tali ẹniti a yàn, ti ireti alãye wà fun: nitoripe ãye ajá san jù okú kiniun lọ.
5Nitori alãye mọ̀ pe awọn o kú; ṣugbọn awọn okú kò mọ̀ ohun kan, bẹ̃ni nwọn kì ili ère mọ; nitori iranti wọn ti di igbagbe.
6Ifẹ wọn pẹlu, ati irira wọn, ati ilara wọn, o parun nisisiyi; bẹ̃ni nwọn kò si ni ipin mọ lailai ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn.
7Ma ba tirẹ lọ, ma fi ayọ̀ jẹ onjẹ rẹ, ki o si mã fi inu-didun mu ọti-waini rẹ: nitoripe Ọlọrun tẹwọgba iṣẹ rẹ nisisiyi.
8Jẹ ki aṣọ rẹ ki o ma fún nigbagbogbo; ki o má si jẹ ki ori rẹ ki o ṣe alaini ororo ikunra,
9Ma fi ayọ̀ ba aya rẹ gbe ti iwọ fẹ ni gbogbo ọjọ aiye asan rẹ, ti o fi fun ọ labẹ õrùn ni gbogbo ọjọ asan rẹ: nitori eyini ni ipin tirẹ li aiye yi, ati ninu lãla ti iwọ ṣe labẹ õrùn.
10Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.
11Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn.
12Nitoripe enia pẹlu kò mọ̀ ìgba tirẹ̀; bi ẹja ti a mu ninu àwọn buburu, ati bi ẹiyẹ ti a mu ninu okùn; bẹ̃li a ndẹ awọn ọmọ enia ni ìgba buburu, nigbati o ṣubu lù wọn lojiji.
13Ọgbọ́n yi ni mo ri pẹlu labẹ õrùn, o si dabi ẹnipe o tobi fun mi.
14Ilu kekere kan wà, ati enia diẹ ninu rẹ̀; ọba nla kan si ṣigun tọ̀ ọ lọ, o si dótì i, o si mọ ile-iṣọ ti o tobi tì i.
15A si ri ọkunrin talaka ọlọgbọ́n ninu rẹ̀, on si fi ọgbọ́n rẹ̀ gbà ilu na silẹ; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o ranti ọkunrin talaka na.
16Nigbana ni mo wipe, Ọgbọ́n san jù agbara lọ; ṣugbọn a kẹgan ọgbọ́n ọkunrin talaka na, ohùn rẹ̀ kò si to òke.
17A ngbọ́ ọ̀rọ ọlọgbọ́n enia ni pẹlẹ jù igbe ẹniti njẹ olori ninu awọn aṣiwère.
18Ọgbọ́n san jù ohun-elo ogun: ṣugbọn ẹ̀lẹṣẹ kan o ba ohun didara pupọ jẹ.