Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
28 verses
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, iwọ ngbe ãrin ọlọ̀tẹ ile, ti nwọn ni oju lati ri, ti kò si ri; nwọn ni eti lati gbọ́, nwọn kò si gbọ́: nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.
3Nitorina, iwọ ọmọ enia, mura nkan kikolọ, ki o si kó lọ li oju wọn li ọsan; ki o si kó lati ipò rẹ lọ si ibomiran li oju wọn; o le ṣe pe nwọn o ronu, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile.
4Ki o si mu nkan rẹ jade li ọsan li oju wọn, bi nkan kikolọ; ki o si jade lọ li aṣalẹ li oju wọn, bi awọn ti nlọ si igbekùn.
5Da ogiri lu loju wọn, ki o si kó jade nibẹ.
6Li oju wọn ni ki o rù u le ejika rẹ, ki o si rù u lọ ni wiriwiri alẹ, ki o si bo oju rẹ, ki o má ba ri ilẹ; nitori mo ti gbe ọ kalẹ fun àmi si ile Israeli.
7Mo si ṣe bi a ti paṣẹ fun mi: mo mu nkan mi jade li ọsan, bi nkan fun igbekùn, mo si fi ọwọ́ mi dá ogiri lu li aṣalẹ; mo gbe e jade ni wiriwiri alẹ, mo si rù u le ejika mi loju wọn.
8Li owurọ ọ̀rọ Oluwa si ti tọ̀ mi wá, wipe,
9Ọmọ enia, ile Israeli, ọlọ̀tẹ ile nì kò ti wi fun ọ pe, kini iwọ nṣe?
10Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹrù yi hàn fun awọn ọmọ-alade ni Jerusalemu, ati gbogbo ile Israeli ti o wà lãrin wọn.
11Wipe, emi ni àmi nyin, gẹgẹ bi mo ti ṣe, bẹ̃ni a o si ṣe si wọn: nwọn o ko kuro, nwọn o si lọ si igbekùn.
12Ọmọ-alade ti o wà larin wọn yio si rẹrù lori ejika rẹ̀ ni wiriwiri alẹ, yio si jade lọ; nwọn o si dá ogiri lu lati kó jade nibẹ; yio si bo oju rẹ̀, ki o má ba fi oju rẹ̀ ri ilẹ.
13Awọ̀n mi ni emi o si tẹ́ le e lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi: emi o si mu u wá si Babiloni, si ilẹ awọn ara Kaldea; kì yio si ri i, bẹ̃ni yio kú nibẹ.
14Gbogbo awọn ti o yi i ka lati ràn a lọwọ, ati gbogbo ọwọ-ogun rẹ̀, ni emi o tuká si gbogbo afẹ̃fẹ, emi o si yọ idà le wọn.
15Nwọn o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa, nigbati mo ba tú wọn ka lãrin awọn orilẹ-ède; ti mo ba si fọ́n wọn ká ilẹ pupọ.
16Ṣugbọn emi o kù diẹ ninu wọn silẹ lọwọ idà, lọwọ iyàn, ati lọwọ ajakálẹ arùn; ki nwọn le sọ gbogbo ohun ẽri wọn lãrin awọn keferi, nibiti nwọn ba de; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
17Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
18Ọmọ enia, fi ìgbọnriri jẹ onjẹ rẹ, si fi ìwariri ati ikiyesara mu omi rẹ;
19Ki o si sọ fun awọn enia ilẹ na pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn ara Jerusalemu, niti ilẹ Israeli; nwọn o fi ikiyesara jẹ onjẹ wọn, nwọn o si fi iyanu mu omi wọn, ki ilẹ rẹ̀ ki o le di ahoro kuro ninu gbogbo ohun ti o wà ninu rẹ̀, nitori ìwa-ipá gbogbo awọn ti ngbe ibẹ̀.
20Awọn ilu ti a ngbe yio di ofo, ilẹ na yio si di ahoro; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
21Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
22Ọmọ enia, owe wo li ẹnyin ni, ni ilẹ Israeli pe, A fà ọjọ gùn, gbogbo iran di asan?
23Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o jẹ ki owe yi dẹkun, nwọn kì yio si pa a li owe ni Israeli mọ; ṣugbọn wi fun wọn pe, Ọjọ kù si dẹ̀dẹ; ati imuṣẹ gbogbo iran.
24Nitori kì yio si iran asan mọ, kì yio si si afọṣẹ ti npọnni ninu ile Israeli.
25Nitori emi li Oluwa: emi o sọ̀rọ, ọ̀rọ ti emi o sọ yio si ṣẹ, a kì yio fà a gùn mọ; nitori li ọjọ nyin, Ọlọtẹ ile, li emi o sọ ọ̀rọ na, emi o si ṣe e, ni Oluwa Ọlọrun wi.
26Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,
27Ọmọ enia, kiyesi i, awọn ara ile Israeli wipe, Iran ti o ri, fun ọjọ pupọ ti mbọ̀ ni, o si sọ asọtẹlẹ akoko ti o jina rere.
28Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Kò si ọkan ninu ọ̀rọ mi ti a o fà gùn mọ, ṣugbọn ọ̀rọ ti mo ti sọ yio ṣẹ, ni Oluwa wi.