Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
8 verses
1NIGBATI Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu àjeji ède enia;
2Juda di ibi mimọ́ rẹ̀, Israeli di ijọba rẹ̀.
3Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin.
4Awọn òke nla nfò bi àgbo, ati awọn òke kekèke bi ọdọ- agutan.
5Kili o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin?
6Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekèke bi ọdọ- agutan?
7Warìri, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu.
8Ẹniti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.