Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
7 verses
1NINU ipọnju mi emi kepè Oluwa, o si da mi lohùn.
2Oluwa, gbà ọkàn mi, lọwọ ète eke, ati lọwọ ahọn ẹ̀tan?
3Kini ki a fi fun ọ? tabi kini ki a ṣe si ọ, ahọn ẹ̀tan.
4Ọfà mimu alagbara, ti on ti ẹyin-iná igi juniperi!
5Egbe ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meṣeki, ti mo joko ninu agọ Kedari!
6O ti pẹ ti ọkàn mi ti ba ẹniti o korira alafia gbe.
7Alafia ni mo fẹ: ṣugbọn nigbati mo ba sọ̀rọ, ija ni ti wọn.