Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
9 verses
1INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa.
2Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu.
3Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan.
4Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa.
5Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi.
6Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere.
7Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ.
8Nitori awọn arakunrin ati awọn ẹgbẹ mi, emi o wi nisisiyi pe, Ki alafia ki o wà ninu rẹ!
9Nitori ile Oluwa Ọlọrun wa, emi o ma wá ire rẹ.