Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
8 verses
1IBA máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, ki Israeli ki o ma wi nisisiyi;
2Iba máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, nigbati awọn enia duro si wa:
3Nigbana ni nwọn iba gbé wa mì lãye, nigbati ibinu nwọn ru si wa:
4Nigbana li omi wọnni iba bò wa mọlẹ, iṣan omi iba ti bori ọkàn wa:
5Nigbana li agberaga omi iba bori ọkàn wa.
6Olubukún li Oluwa, ti kò fi wa fun wọn bi ohun ọdẹ fun ehin wọn.
7Ọkàn wa yọ bi ẹiyẹ jade kuro ninu okùn apẹiyẹ: okùn já, awa si yọ.
8Iranlọwọ wa mbẹ li orukọ Oluwa, ti o da ọrun on aiye.