Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
6 verses
1NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá.
2Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn.
3Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀.
4Oluwa mu ikólọ wa pada, bi iṣan-omi ni gusu.
5Awọn ti nfi omije fún irugbin yio fi ayọ ka.
6Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ̀ pada wá, yio si rù iti rẹ̀.