Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
9 verses
1LI ẹba odò Babeli, nibẹ li awa gbe joko, awa si sọkun nigbati awa ranti Sioni.
2Awa fi duru wa kọ́ si ori igi wíllo ti o wà lãrin rẹ̀.
3Nitoripe nibẹ li awọn ti o kó wa ni igbekun bère orin lọwọ wa; ati awọn ti o ni wa lara bère idaraya wipe; Ẹ kọ orin Sioni kan fun wa.
4Awa o ti ṣe kọ orin Oluwa ni ilẹ àjeji?
5Jerusalemu, bi emi ba gbagbe rẹ, jẹ ki ọwọ ọtún mi ki o gbagbe ìlò rẹ̀.
6Bi emi kò ba ranti rẹ, jẹ ki ahọn mi ki o lẹ̀ mọ èrìgì mi; bi emi kò ba fi Jerusalemu ṣaju olori ayọ̀ mi gbogbo.
7Oluwa, ranti ọjọ Jerusalemu lara awọn ọmọ Edomu, awọn ẹniti nwipe, Wó o palẹ, wó o palẹ, de ipilẹ rẹ̀!
8Iwọ, ọmọbinrin Babeli, ẹniti a o parun; ibukún ni fun ẹniti o san a fun ọ bi iwọ ti hù si wa.
9Ibukún li ẹniti o mu, ti o si fi ọmọ wẹwẹ rẹ ṣán okuta.