Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
5 verses
1OLUWA, tani yio ma ṣe atipo ninu agọ rẹ? tani yio ma gbe inu òke mimọ́ rẹ?
2Ẹniti o nrìn dede, ti nṣiṣẹ ododo, ti o si nsọ otitọ inu rẹ̀.
3Ẹniti kò fi ahọn rẹ̀ sọ̀rọ ẹni lẹhin, ti kò si ṣe ibi si ẹnikeji rẹ̀, ti kò si gbà ọ̀rọ ẹ̀gan si ẹnikeji rẹ̀.
4Li oju ẹniti enia-kenia di gigàn; ṣugbọn a ma bu ọla fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa. Ẹniti o bura si ibi ara rẹ̀, ti kò si yipada.
5Ẹniti kò fi owo rẹ̀ gbà èle, ti kò si gbà owo ẹ̀bẹ si alaiṣẹ. Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi kì yio yẹsẹ lailai.