Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
6 verses
1Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Ọlọrun ninu ibi mimọ́ rẹ̀; yìn i ninu ofurufu oju-ọrun agbara rẹ̀.
2Yìn i nitori iṣẹ agbara rẹ̀: yìn i gẹgẹ bi titobi nla rẹ̀.
3Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i.
4Fi ìlu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i.
5Ẹ yìn i lara aro olohùn òke: ẹ yìn i lara aro olohùn goro:
6Jẹ ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yìn Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.