Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
8 verses
1OLUWA, awọn ti nyọ mi li ẹnu ti npọ̀ to yi! ọ̀pọlọpọ li awọn ti o dide si mi.
2Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun.
3Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke.
4Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá.
5Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin,
6Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka.
7Dide Oluwa; gbà mi, Ọlọrun mi: nitori iwọ li o lù gbogbo awọn ọta mi li egungun ẹrẹkẹ; iwọ si ká ehin awọn enia buburu.
8Ti Oluwa ni igbala: ibukún rẹ si mbẹ lara awọn enia rẹ.