Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
5 verses
1ỌLỌRUN, yara gbà mi; Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ.
2Ki oju ki o tì awọn ti nwá ọkàn mi, ki nwọn ki o si dãmu: ki nwọn ki o si pada sẹhin, ki a si dãmu awọn ti nwá ifarapa mi.
3Ki a pa wọn li ẹhìn dà fun ère itiju awọn ti nwi pe, A! a!
4Ki gbogbo awọn ti nwá ọ ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn nipa tirẹ: ki iru awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Ki a gbé Ọlọrun ga!
5Ṣugbọn talaka ati alaini li emi: Ọlọrun, yara si mi: iwọ li oluranlọwọ ati olugbala mi: Oluwa, máṣe pẹ́ titi.