Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
12 verses
1NI Juda li a gbe mọ̀ Ọlọrun: orukọ rẹ̀ si pọ̀ ni Israeli.
2Ni Salemu pẹlu li agọ rẹ̀ wà, ati ibujoko rẹ̀ ni Sioni.
3Nibẹ li o gbe ṣẹ́ ọfà, ọrun, apata, ati idà, ati ogun na.
4Iwọ li ogo ati ọlá jù òke-nla ikogun wọnni lọ.
5A kó awọn alaiya lile ni ikogun, nwọn ti sùn orun wọn, gbogbo ọkunrin alagbara kò si ri ọwọ wọn.
6Nipa ibawi rẹ, Ọlọrun Jakobu, ati kẹkẹ́-ogun ati ẹṣin sun orun asunkú.
7Iwọ, ani iwọ li o ni ìbẹru: ati tani yio le duro niwaju rẹ, nigbati iwọ ba binu lẹ̃kan?
8Iwọ mu idajọ di gbigbọ́ lati ọrun wá: ilẹ aiye bẹ̀ru o si duro jẹ.
9Nigbati Ọlọrun dide si idajọ, lati gbà gbogbo ọlọkan-tutu aiye là.
10Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure.
11Ẹ ṣe ileri ifẹ, ki ẹ si san a fun Oluwa, Ọlọrun nyin: jẹ ki gbogbo awọn ti o yi i ka ki o mu ẹ̀bun wá fun ẹniti a ba ma bẹ̀ru.
12On o ke ẹmi awọn ọmọ alade kuro: on si di ẹ̀ru si awọn ọba aiye.