Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
8 verses
1ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara; o nṣe idajọ ninu awọn ọlọrun.
2Ẹnyin o ti ṣe idajọ aiṣõtọ pẹ to, ti ẹ o si ma ṣe ojuṣaju awọn enia buburu?
3Ṣe idajọ talaka, ati ti alaini-baba: ṣe otitọ si awọn olupọnju ati alaini.
4Gbà talaka ati alaini: yọ wọn li ọwọ awọn enia buburu.
5Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.
6Emi ti wipe, ọlọrun li ẹnyin; awọn ọmọ Ọga-ogo si ni gbogbo nyin.
7Ṣugbọn ẹnyin o kú bi enia, ẹnyin o si ṣubu bi ọkan ninu awọn ọmọ-alade.
8Ọlọrun, dide, ṣe idajọ aiye: nitori iwọ ni yio ni orilẹ-ède gbogbo.