Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
7 verses
1IPILẸ rẹ̀ mbẹ lori òke mimọ́ wọnni.
2Oluwa fẹ ẹnu-ọ̀na Sioni jù gbogbo ibujoko Jakobu lọ.
3Ohun ogo li a nsọ niti rẹ? Ilu Ọlọrun!
4Emi o da orukọ Rahabu ati Babeli lãrin awọn ti o mọ̀ mi: kiyesi Filistia ati Tire, pẹlu Etiopia: a bi eleyi nibẹ.
5Ati ni Sioni li a o wipe: ọkunrin yi ati ọkunrin nì li a bi ninu rẹ̀: ati Ọga-ogo tikararẹ̀ ni yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ.
6Oluwa yio kà, nigbati o ba nkọ orukọ awọn enia, pe, a bi eleyi nibẹ.
7Ati awọn olorin ati awọn ti nlu ohun-elo orin yio wipe: Gbogbo orisun mi mbẹ ninu rẹ.