Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
13 verses
1MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti on ti okùn- iwọ̀n lọwọ rẹ̀.
2Mo si wipe, Nibo ni iwọ nlọ? o si wi fun mi pe, Lati wọ̀n Jerusalemu, lati ri iye ibú rẹ̀, ati iye gigùn rẹ̀.
3Si kiyesi i, angeli ti o mba mi sọ̀rọ jade lọ, angeli miran si jade lọ ipade rẹ̀.
4O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀:
5Oluwa wipe, Emi o si jẹ odi iná fun u yika, emi o si jẹ ogo lãrin rẹ̀.
6Ã! ã! sá kuro ni ilẹ ariwa, ni Oluwa wi; nitoripe bi afẹfẹ mẹrin ọrun ni mo tu nyin kakiri, ni Oluwa wi.
7Sioni, gba ara rẹ là, iwọ ti o mba ọmọbinrin Babiloni gbe.
8Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; lẹhìn ogo li o ti rán mi si awọn orilẹ-ède ti nkó nyin: nitori ẹniti o tọ́ nyin, o tọ́ ọmọ oju rẹ̀.
9Nitori kiyesi i, emi o gbọ̀n ọwọ mi si ori wọn, nwọn o si jẹ ikogun fun iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi.
10Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi.
11Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ.
12Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu.
13Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.