Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
8 verses
1IGBA pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá, ni ki Israeli ki o wi nisisiyi.
2Igba pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá: sibẹ nwọn kò ti ibori mi.
3Awọn awalẹ̀ walẹ si ẹhin mi: nwọn si la aporo wọn gigun.
4Olododo li Oluwa: o ti ke okùn awọn enia buburu kuro.
5Ki gbogbo awọn ti o korira Sioni ki o dãmu, ki nwọn ki o si yi ẹhin pada.
6Ki nwọn ki o dabi koriko ori-ile ti o gbẹ danu, ki o to dagba soke:
7Eyi ti oloko pipa kò kún ọwọ rẹ̀; bẹ̃li ẹniti ndi ití, kò kún apa rẹ̀.
8Bẹ̃li awọn ti nkọja lọ kò wipe, Ibukún Oluwa ki o pẹlu nyin: awa sure fun nyin li orukọ Oluwa.