Loading Bible Translation
First-time download in progress. This may take a few seconds…
Yoruba Holy Bible Wordproject Bible
8 verses
1LATI inu ibu wá li emi kepe ọ, Oluwa.
2Oluwa, gbohùn mi, jẹ ki eti rẹ ki o tẹ́ silẹ si ohùn ẹ̀bẹ mi.
3Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro?
4Nitori idariji wà lọdọ rẹ, ki a le ma bẹ̀ru rẹ.
5Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọ̀rọ rẹ̀ li emi nṣe ireti.
6Ọkàn mi duro dè Oluwa, jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ, ani jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ.
7Israeli iwọ ni ireti niti Oluwa: nitori pe lọdọ Oluwa li ãnu wà, ati lọdọ rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ idande wà.
8On o si da Israeli nidè kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo,